
Saamu 134
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
1Ẹ kíyèsi i, ẹ fi ìbùkún fún Olúwa, gbogbo ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa, tí ó dúró ní ilé Olúwa ní òru.
2Ẹ gbé ọwọ́ yín sókè sí ibi mímọ́, kí ẹ sì fi ìbùkún fún Olúwa.
3Olúwa tí ó dá ọ̀run òun ayé, kí ó bùsi i fún ọ láti Sioni wá.
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní — CC BY-SA 4.0. Where these translations come from.
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Available free at biblica.com and open.bible. Text unchanged, used under CC BY-SA 4.0.